25 “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Òfin ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ nìyí: Ibi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun+ ni kí wọ́n ti pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níwájú Jèhófà. Ohun mímọ́ jù lọ ni. 26 Àlùfáà tó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ló máa jẹ ẹ́.+ Ibi mímọ́ ni kó ti jẹ ẹ́, nínú àgbàlá àgọ́ ìpàdé.+