-
Ẹ́kísódù 29:38-41Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
38 “Ohun tí ìwọ yóò fi rúbọ lórí pẹpẹ náà nìyí: ọmọ àgbò méjì tó jẹ́ ọlọ́dún kan lójoojúmọ́ títí lọ.+ 39 Kí o fi ọmọ àgbò kan rúbọ ní àárọ̀, kí o sì fi ọmọ àgbò kejì rúbọ ní ìrọ̀lẹ́.*+ 40 Kí o fi ọmọ àgbò àkọ́kọ́ rúbọ pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí: ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* tí o pò mọ́ ìlàrin òṣùwọ̀n hínì* òróró tí wọ́n fún àti ọrẹ ohun mímu tó jẹ́ wáìnì tó kún ìlàrin òṣùwọ̀n hínì. 41 Kí o fi ọmọ àgbò kejì rúbọ ní ìrọ̀lẹ́,* pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti ọrẹ ohun mímu kan náà bíi ti àárọ̀. Kí o fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn,* ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.
-
-
Nọ́ńbà 28:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Kí o mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan wá ní àárọ̀, kí o sì mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kejì wá ní ìrọ̀lẹ́,*+ 5 pẹ̀lú ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* tí wọ́n pò mọ́ òróró tí wọ́n fún tó jẹ́ ìlàrin òṣùwọ̀n hínì* láti fi ṣe ọrẹ ọkà.+ 6 Ẹbọ sísun ìgbà gbogbo+ ni, èyí tí a fi lélẹ̀ ní Òkè Sínáì láti mú òórùn dídùn* jáde, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà,
-