4 Àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ nìyí:+ akọ màlúù, àgùntàn, ewúrẹ́, 5 àgbọ̀nrín, egbin, èsúwó, ẹ̀kìrì,* ẹtu, àgùntàn igbó àti àgùntàn orí àpáta. 6 Ẹ lè jẹ ẹran èyíkéyìí tí pátákò rẹ̀ là sí méjì, tó sì ń jẹ àpọ̀jẹ.
14 Ní mo bá sọ pé: “Rárá o, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Láti kékeré títí di báyìí, mi* ò jẹ òkú ẹran rí tàbí ẹran tí wọ́n fà ya+ tó máa sọ mí di aláìmọ́, mi ò sì jẹ ẹran kankan tó jẹ́ aláìmọ́* rí.”+