16 Bákan náà, kí ẹ máa ṣe Àjọyọ̀ Ìkórè* àwọn èso oko yín tó kọ́kọ́ pọ́n, èyí tí ẹ ṣiṣẹ́ kára láti gbìn;+ àti Àjọyọ̀ Ìkórèwọlé* níparí ọdún, nígbà tí ẹ bá kórè gbogbo ohun tí ẹ gbìn sí oko.+
26 “‘Ní ọjọ́ àkọ́pọ́n èso,+ tí ẹ bá mú ọrẹ ọkà tuntun wá fún Jèhófà,+ kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́ nígbà tí ẹ bá ń ṣe àsè àwọn ọ̀sẹ̀.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára+ kankan.