-
Léfítíkù 1:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 “‘Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ẹyẹ ló fẹ́ mú wá láti fi rú ẹbọ sísun sí Jèhófà, kó mú ọrẹ rẹ̀ wá látinú àwọn ẹyẹ oriri tàbí ọmọ ẹyẹlé.+
-
-
Léfítíkù 14:21, 22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 “Àmọ́, tó bá jẹ́ aláìní, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́, kó mú ọmọ àgbò kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi, kó fi ṣe ọrẹ fífì, kó lè ṣe ètùtù fún ara rẹ̀, pẹ̀lú ìyẹ̀fun tó kúnná, tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà,* tí wọ́n pò mọ́ òróró láti fi ṣe ọrẹ ọkà, òróró tó kún òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì kan, 22 àti ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, èyí tí agbára rẹ̀ bá gbé. Ọ̀kan máa jẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, èkejì á sì jẹ́ ẹbọ sísun.+
-