-
Nọ́ńbà 12:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Jèhófà dá Mósè lóhùn pé: “Tó bá jẹ́ bàbá rẹ̀ ló tutọ́ sí i lójú, ǹjẹ́ ọjọ́ méje kọ́ lojú fi máa tì í? Ẹ lọ sé e mọ́ ẹ̀yìn ibùdó+ fún ọjọ́ méje, lẹ́yìn náà, kí ẹ jẹ́ kó wọlé.”
-
-
2 Àwọn Ọba 7:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́rin kan wà ní ibi àtiwọ ẹnubodè ìlú,+ wọ́n sì sọ fún ara wọn pé: “Kí nìdí tí a fi máa jókòó síbí títí a ó fi kú?
-
-
2 Kíróníkà 26:20, 21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Nígbà tí Asaráyà olórí àlùfáà àti gbogbo àlùfáà yíjú sí i, wọ́n rí i pé ẹ̀tẹ̀ ti kọ lù ú níwájú orí! Nítorí náà, wọ́n sáré mú un jáde kúrò níbẹ̀, òun náà sì tètè jáde, nítorí Jèhófà ti kọ lù ú.
21 Ọba Ùsáyà ya adẹ́tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, ilé tó wà lọ́tọ̀ ló sì ń gbé torí pé adẹ́tẹ̀ ni,+ wọn ò sì jẹ́ kó wá sí ilé Jèhófà mọ́. Jótámù ọmọ rẹ̀ ló wá ń bójú tó ilé* ọba, ó sì ń dá ẹjọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà.+
-