13 “‘Tí ohun tó ń dà náà bá dáwọ́ dúró, tí ẹni náà sì wá mọ́ kúrò nínú rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ méje, lẹ́yìn náà kó di mímọ́, kó fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, yóò sì di mímọ́.+ 14 Ní ọjọ́ kẹjọ, kó mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé+ méjì, kó wá síwájú Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kó sì kó wọn fún àlùfáà.