-
Léfítíkù 14:15-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Kí àlùfáà mú lára òróró òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì + náà, kó sì dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀. 16 Kí àlùfáà wá ki ìka ọ̀tún rẹ̀ bọ òróró tó wà ní àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀, kó sì fi ìka rẹ̀ wọ́n lára òróró náà lẹ́ẹ̀méje níwájú Jèhófà. 17 Kí àlùfáà wá fi lára òróró tó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún ẹni náà tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́ àti àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ lórí ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi. 18 Kí àlùfáà fi èyí tó ṣẹ́ kù lára òróró tó wà ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sí orí ẹni tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́, kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà.+
-