-
Léfítíkù 15:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ní ọjọ́ kẹjọ, kó mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé+ méjì, kó wá síwájú Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kó sì kó wọn fún àlùfáà. 15 Kí àlùfáà sì fi wọ́n rúbọ, kó fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kó fi èkejì rú ẹbọ sísun, kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà torí ohun tó ń dà jáde lára rẹ̀.
-