-
Léfítíkù 16:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 “Kó mú òbúkọ méjì tó ṣì kéré látinú àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kó sì fi àgbò kan rú ẹbọ sísun.
-
-
Hébérù 5:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Torí gbogbo àlùfáà àgbà tí a mú láàárín àwọn èèyàn ni a yàn nítorí wọn láti bójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ọlọ́run,+ kó lè fi àwọn ọrẹ àti ẹbọ rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀.+ 2 Ó ṣeé ṣe fún un láti ṣàánú àwọn aláìmọ̀kan* àti àwọn tó ń ṣàṣìṣe,* torí òun náà ní àìlera tiẹ̀,* 3 ìdí nìyẹn tí òun náà fi gbọ́dọ̀ rú ẹbọ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiẹ̀, bó ṣe ń ṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn gẹ́lẹ́.+
-