-
Diutarónómì 20:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Ṣe ni kí o pa wọ́n run pátápátá, ìyẹn àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe pa á láṣẹ fún ọ gẹ́lẹ́; 18 kí wọ́n má bàa kọ́ yín láti máa ṣe gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, kí wọ́n wá mú kí ẹ ṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín.+
-
-
2 Àwọn Ọba 16:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ẹni ogún (20) ọdún ni Áhásì nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Kò ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+ 3 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ kódà ó sun ọmọ rẹ̀ nínú iná,+ ó tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe.
-