44 Torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín,+ ẹ gbọ́dọ̀ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì di mímọ́,+ torí mo jẹ́ mímọ́.+ Torí náà, ẹ ò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀dá èyíkéyìí tó ń gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀ sọ ara yín* di aláìmọ́.
8 Ní ti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìyẹ́ mẹ́fà tí ojú kún ara rẹ̀ yí ká àti lábẹ́.+ Tọ̀sántòru ni wọ́n ń sọ pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà*+ Ọlọ́run, Olódùmarè, tó ti wà tipẹ́, tó wà báyìí, tó sì ń bọ̀.”+