Ẹ́kísódù 20:12 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 12 “Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ,+ kí ẹ̀mí rẹ lè gùn lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.+ Éfésù 6:2 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 2 “Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ,”+ èyí ni àṣẹ kìíní pẹ̀lú ìlérí: Hébérù 12:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 Bákan náà, àwọn bàbá tó bí wa* máa ń bá wa wí, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Ṣé kò wá yẹ kó yá wa lára láti fi ara wa sábẹ́ Baba tó ni ìgbésí ayé wa nípa ti ẹ̀mí, ká lè máa wà láàyè?+
9 Bákan náà, àwọn bàbá tó bí wa* máa ń bá wa wí, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Ṣé kò wá yẹ kó yá wa lára láti fi ara wa sábẹ́ Baba tó ni ìgbésí ayé wa nípa ti ẹ̀mí, ká lè máa wà láàyè?+