13 Àmọ́ tí ẹnì kan bá wà ní mímọ́ tàbí tí kò rìnrìn àjò, tó sì kọ̀ láti ṣètò ẹbọ Ìrékọjá, ṣe ni kí ẹ pa ẹni* náà, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀,+ torí kò mú ọrẹ Jèhófà wá ní àkókò rẹ̀. Ẹni náà yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
30 “‘Ṣùgbọ́n ẹni* tó bá mọ̀ọ́mọ̀ ṣe+ ohun kan ń kó ẹ̀gàn bá Jèhófà, ì báà jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àjèjì, torí náà, ṣe ni kí ẹ pa á, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.