ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 12:49
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 49 Òfin kan náà ni kí ọmọ ìbílẹ̀ àti àjèjì tó ń gbé láàárín yín máa tẹ̀ lé.”+

  • Léfítíkù 17:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 “‘Tí ọkùnrin kankan ní ilé Ísírẹ́lì tàbí tí àjèjì kankan tó ń gbé láàárín yín bá jẹ ẹ̀jẹ̀+ èyíkéyìí, ó dájú pé mi ò ní fi ojú rere wo ẹni* tó ń jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi yóò sì pa á, kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.

  • Léfítíkù 19:34
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 34 Kí ẹ máa ṣe àjèjì tó ń bá yín gbé bí ọmọ ìbílẹ̀;+ kí ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ara yín, torí àjèjì lẹ jẹ́ ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.

  • Nọ́ńbà 9:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 “‘Tí àjèjì kan bá ń gbé lọ́dọ̀ yín, kí òun náà ṣètò ẹbọ Ìrékọjá fún Jèhófà.+ Kó tẹ̀ lé àṣẹ àti ìlànà tó wà fún Ìrékọjá láti ṣètò rẹ̀.+ Àṣẹ kan náà ni kí ẹ máa tẹ̀ lé, ì báà jẹ́ àjèjì tàbí ọmọ ìbílẹ̀.’”+

  • Nọ́ńbà 15:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Òfin kan náà àti ìdájọ́ kan náà ni kí ẹ̀yin àti àjèjì tí ẹ jọ ń gbé máa tẹ̀ lé.’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́