-
Nọ́ńbà 15:27-29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 “‘Tí ẹnikẹ́ni* bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, kó mú abo ewúrẹ́ ọlọ́dún kan wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+ 28 Kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún ẹni* tó ṣe àṣìṣe náà, tó ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀ níwájú Jèhófà, kó lè ṣe ètùtù fún un, ó sì máa rí ìdáríjì.+ 29 Òfin kan náà ni kí ọmọ ìbílẹ̀ Ísírẹ́lì àti àjèjì tí wọ́n jọ ń gbé máa tẹ̀ lé tí ẹnì kan bá ṣe ohun kan láìmọ̀ọ́mọ̀.+
-