2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú tí wọ́n á máa gbé látinú ogún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gbà,+ kí wọ́n sì fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ibi ìjẹko tó yí àwọn ìlú+ náà ká.
8 Látinú ohun ìní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ ni kí ẹ ti fún wọn ní àwọn ìlú náà. Kí ẹ gba púpọ̀ lọ́wọ́ àwùjọ tó pọ̀, kí ẹ sì gba díẹ̀+ lọ́wọ́ àwùjọ tó kéré. Kí àwùjọ kọ̀ọ̀kan fún àwọn ọmọ Léfì lára àwọn ìlú rẹ̀ bí ogún tó gbà bá ṣe pọ̀ tó.”