ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 15:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 “Tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ bá di aláìní láàárín rẹ nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, o ò gbọ́dọ̀ mú kí ọkàn rẹ le tàbí kí o háwọ́ sí arákùnrin rẹ tó jẹ́ aláìní.+

  • Sáàmù 41:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 41 Aláyọ̀ ni ẹni tó bá ń ro ti àwọn aláìní;+

      Jèhófà yóò gbà á sílẹ̀ ní ọjọ́ àjálù.

  • Sáàmù 112:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 Nǹkan máa ń lọ dáadáa fún ẹni tó bá ń yáni ní nǹkan tọkàntọkàn.*+

      י [Yódì]

      Ìdájọ́ òdodo ló fi ń ṣe nǹkan.

  • Òwe 3:27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó yẹ kí o ṣe é fún*+

      Tó bá wà níkàáwọ́ rẹ* láti ṣe é.+

  • Òwe 19:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan,+

      Á sì san án* pa dà fún un nítorí ohun tó ṣe.+

  • Máàkù 14:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Torí ìgbà gbogbo ni àwọn aláìní wà láàárín yín,+ ẹ sì lè ṣe ohun rere sí wọn nígbàkigbà tí ẹ bá fẹ́, àmọ́ ìgbà gbogbo kọ́ ni màá wà láàárín yín.+

  • Ìṣe 11:29
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 29 Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn pinnu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí agbára kálukú wọn gbé,+ láti fi nǹkan ìrànwọ́*+ ránṣẹ́ sí àwọn ará tó ń gbé ní Jùdíà;

  • 1 Tímótì 6:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Sọ fún wọn pé kí wọ́n máa ṣe rere, àní kí wọ́n máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere, kí wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́,* kí wọ́n ṣe tán láti máa fúnni,+

  • 1 Jòhánù 3:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ní ohun ìní ayé yìí, tó sì rí i pé arákùnrin rẹ̀ ṣaláìní síbẹ̀ tí kò ṣàánú rẹ̀, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe wà nínú rẹ̀?+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́