-
Àwọn Onídàájọ́ 7:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Gbàrà tí Gídíónì gbọ́ tó rọ́ àlá náà, tó sì gbọ́ ìtumọ̀ rẹ̀,+ ó forí balẹ̀, ó sì jọ́sìn. Lẹ́yìn náà, ó pa dà sí ibùdó Ísírẹ́lì, ó sì sọ pé: “Ẹ dìde, torí Jèhófà ti fi ibùdó Mídíánì lé yín lọ́wọ́.” 16 Ó wá pín ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin náà sí àwùjọ mẹ́ta, ó fún gbogbo wọn ní ìwo+ àti ìṣà ńlá tó ṣófo, ògùṣọ̀ sì wà nínú àwọn ìṣà náà.
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 15:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Ó rí egungun tútù kan tó jẹ́ egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; ó na ọwọ́ mú un, ó sì fi ṣá ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin balẹ̀.+ 16 Sámúsìn wá sọ pé:
“Pẹ̀lú egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, òkìtì kan, òkìtì méjì!
Mo fi egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ṣá ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin balẹ̀.”+
-