-
Léfítíkù 11:21-24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 “‘Nínú àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ tó ń gbá yìn-ìn, tó ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, àwọn tó ní tete lókè ẹsẹ̀ wọn láti máa fi tọ lórí ilẹ̀ nìkan ni ẹ lè jẹ. 22 Èyí tí ẹ lè jẹ nínú wọn nìyí: onírúurú eéṣú tó máa ń ṣí kiri, àwọn eéṣú míì tó ṣeé jẹ,+ ìrẹ̀ àti tata. 23 Gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́ yòókù tó ń gbá yìn-ìn, tó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin jẹ́ ohun ìríra fún yín. 24 Ẹ lè fi nǹkan wọ̀nyí sọ ara yín di aláìmọ́. Gbogbo ẹni tó bá fara kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́.+
-
-
Diutarónómì 14:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Bákan náà ni ẹlẹ́dẹ̀, torí pátákò rẹ̀ là, àmọ́ kì í jẹ àpọ̀jẹ. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín. Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹran wọn, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn.
-