-
Jóṣúà 17:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Àmọ́ Sélóféhádì,+ ọmọ Héfà, ọmọ Gílíádì, ọmọ Mákírù, ọmọ Mánásè kò bímọ ọkùnrin, obìnrin nìkan ló bí, orúkọ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ sì nìyí: Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tírísà. 4 Wọ́n wá lọ bá àlùfáà Élíásárì,+ Jóṣúà ọmọ Núnì àti àwọn ìjòyè, wọ́n sì sọ pé: “Jèhófà ló pàṣẹ fún Mósè pé kó fún wa ní ogún láàárín àwọn arákùnrin wa.”+ Torí náà, ó fún wọn ní ogún láàárín àwọn arákùnrin bàbá wọn, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ.+
-