29 Ẹ kíyè sí i pé Jèhófà ti fún yín ní Sábáàtì.+ Ìdí nìyẹn tó fi fún yín ní oúnjẹ ọjọ́ méjì ní ọjọ́ kẹfà. Kí kálukú dúró sí ibi tó bá wà; ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ kúrò ní agbègbè rẹ̀ ní ọjọ́ keje.”
10 àmọ́ ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ. O ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kankan, ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ àti ọmọbìnrin rẹ àti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ àti ẹran ọ̀sìn rẹ àti àjèjì tí ẹ jọ ń gbé.*+