-
Ẹ́kísódù 29:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Kí o tún mú búrẹ́dì ribiti kan àti búrẹ́dì tí wọ́n fi òróró sí tó rí bí òrùka àti búrẹ́dì pẹlẹbẹ kan látinú apẹ̀rẹ̀ búrẹ́dì aláìwú tó wà níwájú Jèhófà. 24 Kí o kó gbogbo wọn sí ọwọ́ Áárónì àti sí ọwọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, kí o sì fì wọ́n síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà.
-