-
Nọ́ńbà 7:13-17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì* àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,*+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+ 14 ife wúrà* kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀; 15 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ sísun;+ 16 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 17 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Náṣónì ọmọ Ámínádábù+ mú wá.
-