2 “Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàgọ́ síbi tí wọ́n pín àwọn ẹ̀yà wọn sí ní mẹ́ta-mẹ́ta,+ kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan pàgọ́ síbi àkọlé* agbo ilé bàbá rẹ̀. Kí àgọ́ wọn dojú kọ àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n pàgọ́ yí i ká.
34 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè. Báyìí ni wọ́n ṣe ń pàgọ́, lọ́nà mẹ́ta-mẹ́ta tí wọ́n pín ẹ̀yà wọn sí,+ tí wọ́n sì máa ń tú àgọ́ wọn ká,+ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn.