4 Onírúurú èèyàn+ tó wà láàárín wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn+ wọn hàn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà tún wá ń sunkún, wọ́n sì ń sọ pé: “Ta ló máa fún wa ní ẹran jẹ?+ 5 A ò jẹ́ gbàgbé ẹja tí a máa ń jẹ lọ́fẹ̀ẹ́ nílẹ̀ Íjíbítì àti kùkúńbà, bàrà olómi, ewébẹ̀ líìkì, àlùbọ́sà àti ááyù!+