22 “Àmọ́ gbogbo yín wá bá mi, ẹ sì sọ pé, ‘Jẹ́ ká rán àwọn ọkùnrin lọ ṣáájú wa, kí wọ́n lè bá wa wo ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì pa dà wá jábọ̀ fún wa, ká lè mọ ọ̀nà tí a máa gbà àtàwọn ìlú tó wà lọ́nà.’+ 23 Àbá yẹn dáa lójú mi, mo sì yan ọkùnrin méjìlá (12) lára yín, ẹnì kan látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.+