11 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ èso ilẹ̀ náà ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé Ìrékọjá, wọ́n jẹ búrẹ́dì aláìwú+ àti àyangbẹ ọkà lọ́jọ́ yẹn kan náà. 12 Mánà ò rọ̀ fún wọn ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé ọjọ́ tí wọ́n jẹ lára èso ilẹ̀ náà; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò rí mánà kó mọ́,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ èso ilẹ̀ Kénáánì ní ọdún yẹn.+