44 Torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín,+ ẹ gbọ́dọ̀ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì di mímọ́,+ torí mo jẹ́ mímọ́.+ Torí náà, ẹ ò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀dá èyíkéyìí tó ń gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀ sọ ara yín* di aláìmọ́.
12Nítorí náà, mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín, ẹ̀yin ará, pé kí ẹ fi ara yín+ fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, tó jẹ́ mímọ́,+ tó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, kí ẹ lè ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ pẹ̀lú agbára ìrònú yín.+