-
Hébérù 9:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Àgọ́ yìí jẹ́ àpèjúwe fún àkókò yìí,+ a sì ń fi àwọn ọrẹ àti ẹbọ rúbọ ní ìbámu pẹ̀lú ètò yìí.+ Àmọ́ àwọn yìí ò lè mú kí ẹni tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ pátápátá.+ 10 Kìkì ohun tí wọ́n dá lé lórí ni oúnjẹ, ohun mímu àti oríṣiríṣi ìwẹ̀* tí òfin sọ.+ Wọ́n jẹ́ àwọn ohun tí òfin béèrè ní ti ara,+ a sì sọ ọ́ di dandan títí di àkókò tí a yàn láti mú àwọn nǹkan tọ́.
-
-
Hébérù 9:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Torí tí ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ màlúù+ àti eérú ọmọ màlúù* tí wọ́n fi wọ́n àwọn tó ti di aláìmọ́ bá sọ wọ́n di mímọ́ kó lè wẹ ẹran ara mọ́,+ 14 ǹjẹ́ ẹ̀jẹ̀ Kristi,+ ẹni tó tipasẹ̀ ẹ̀mí àìnípẹ̀kun fi ara rẹ̀ rúbọ sí Ọlọ́run láìní àbààwọ́n kò ní ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ láti wẹ ẹ̀rí ọkàn wa mọ́ kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́,+ ká lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run alààyè?+
-