-
Diutarónómì 2:30-35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Àmọ́ Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì kò jẹ́ ká kọjá, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ gbà á láyè pé kó ṣorí kunkun,+ kí ọkàn rẹ̀ sì le, kó lè fi í lé ọ lọ́wọ́ bó ṣe rí báyìí. +
31 “Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Wò ó, mo ti ń fi Síhónì àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Bẹ̀rẹ̀ sí í gba ilẹ̀ rẹ̀.’+ 32 Nígbà tí Síhónì àti gbogbo èèyàn rẹ̀ jáde wá gbógun jà wá ní Jáhásì,+ 33 Jèhófà Ọlọ́run wa fi í lé wa lọ́wọ́, a sì ṣẹ́gun òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo èèyàn rẹ̀. 34 A gba gbogbo ìlú rẹ̀ nígbà yẹn, a sì pa gbogbo ìlú náà run, títí kan àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé. A ò dá ẹnikẹ́ni sí.+ 35 Àwọn ẹran ọ̀sìn nìkan la kó bọ̀ láti ogun pẹ̀lú àwọn ẹrù tí a kó láti àwọn ìlú tí a ṣẹ́gun.
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 11:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 “‘Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì ránṣẹ́ sí Síhónì ọba àwọn Ámórì, ọba Hẹ́ṣíbónì, Ísírẹ́lì sì sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ ká gba ilẹ̀ rẹ kọjá sí àyè wa.”+ 20 Àmọ́ Síhónì kò fọkàn tán Ísírẹ́lì, kò gbà kí wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀ kọjá, torí náà, Síhónì kó gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ jọ, wọ́n pàgọ́ sí Jáhásì, wọ́n sì bá Ísírẹ́lì jà.+
-