33 Mósè fún àwọn ọmọ Gádì, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì+ àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ ọmọ Jósẹ́fù ní ilẹ̀ tí Síhónì+ ọba àwọn Ámórì ti ń jọba àti ilẹ̀ ti Ógù+ ọba Báṣánì ti ń jọba, ilẹ̀ tó wà láwọn ìlú rẹ̀ ní àwọn agbègbè yẹn àti àwọn ìlú tó yí ilẹ̀ náà ká.
22 “O fún wọn ní àwọn ìjọba àti àwọn èèyàn, o sì pín wọn ní ẹyọ-ẹyọ fún wọn,+ kí wọ́n lè gba ilẹ̀ Síhónì,+ ìyẹn ilẹ̀ ọba Hẹ́ṣíbónì+ àti ilẹ̀ Ógù+ ọba Báṣánì.