-
Nọ́ńbà 22:23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí áńgẹ́lì Jèhófà tó dúró sójú ọ̀nà, tó ti fa idà yọ, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fẹ́ yà kúrò lọ́nà kó lè gba inú igbó. Àmọ́ Báláámù bẹ̀rẹ̀ sí í lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà kó lè dá a pa dà sójú ọ̀nà.
-
-
Nọ́ńbà 22:25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí áńgẹ́lì Jèhófà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rún ara rẹ̀ mọ́ ògiri náà, ó sì gbá ẹsẹ̀ Báláámù mọ́ ògiri náà, Báláámù wá túbọ̀ ń lù ú.
-
-
Nọ́ńbà 22:27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí áńgẹ́lì Jèhófà, ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ Báláámù, inú wá bí Báláámù gan-an, ó sì ń fi ọ̀pá rẹ̀ lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.
-