-
Nọ́ńbà 16:39, 40Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
39 Àlùfáà Élíásárì wá kó àwọn ìkóná tí wọ́n fi bàbà ṣe, èyí tí àwọn tó jóná náà mú wá, ó sì fi wọ́n rọ ohun tí wọ́n á fi máa bo pẹpẹ, 40 bí Jèhófà ṣe gbẹnu Mósè sọ fún un. Yóò máa rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé ẹnikẹ́ni tí kò tọ́ sí,* tí kì í ṣe ọmọ Áárónì kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti sun tùràrí níwájú Jèhófà+ àti pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ dà bíi Kórà àti àwọn tó ń tì í lẹ́yìn.+
-
-
2 Kíróníkà 26:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Àmọ́, bó ṣe di alágbára tán, ìgbéraga wọ̀ ọ́ lẹ́wù débi tó fi fa àjálù bá ara rẹ̀, ó hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bó ṣe wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí.+
-
-
2 Kíróníkà 26:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Wọ́n kojú Ọba Ùsáyà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ùsáyà, kò tọ́ sí ọ láti sun tùràrí sí Jèhófà!+ Àwọn àlùfáà nìkan ló yẹ kó máa sun tùràrí, torí àwọn ni àtọmọdọ́mọ Áárónì,+ àwọn tí a ti yà sí mímọ́. Jáde kúrò ní ibi mímọ́, nítorí o ti hùwà àìṣòótọ́, o ò sì ní rí ògo kankan gbà lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run nítorí èyí.”
-