33 Mósè fún àwọn ọmọ Gádì, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì+ àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ ọmọ Jósẹ́fù ní ilẹ̀ tí Síhónì+ ọba àwọn Ámórì ti ń jọba àti ilẹ̀ ti Ógù+ ọba Báṣánì ti ń jọba, ilẹ̀ tó wà láwọn ìlú rẹ̀ ní àwọn agbègbè yẹn àti àwọn ìlú tó yí ilẹ̀ náà ká.
7 Nígbà tí ẹ wá dé ibí yìí, Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì+ àti Ógù ọba Báṣánì+ jáde wá bá wa jagun, àmọ́ a ṣẹ́gun wọn.+8 Lẹ́yìn náà, a gba ilẹ̀ wọn, a sì fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà àwọn ọmọ Mánásè+ pé kó jẹ́ ogún tiwọn.
29 Yàtọ̀ síyẹn, Mósè pín ogún fún ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, ìdajì nínú ẹ̀yà Mánásè ní ìdílé-ìdílé.+30 Ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Máhánáímù+ tó fi mọ́ gbogbo Báṣánì, gbogbo ilẹ̀ Ógù ọba Báṣánì àti gbogbo abúlé Jáírì+ tí wọ́n pàgọ́ sí ní Báṣánì, ó jẹ́ ọgọ́ta (60) ìlú.