12 Bí wọ́n ṣe fi Jèhófà, Ọlọ́run àwọn bàbá wọn sílẹ̀ nìyẹn, ẹni tó mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Wọ́n wá tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, àwọn ọlọ́run àwọn èèyàn tó yí wọn ká,+ wọ́n forí balẹ̀ fún wọn, wọ́n sì múnú bí Jèhófà.+
20 Níkẹyìn, Jèhófà bínú gidigidi sí Ísírẹ́lì,+ ó sì sọ pé: “Torí pé orílẹ̀-èdè yìí ti da májẹ̀mú mi+ tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá wọn, tí wọn kò sì fetí sí mi,+