12 Bí wọ́n ṣe fi Jèhófà, Ọlọ́run àwọn bàbá wọn sílẹ̀ nìyẹn, ẹni tó mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Wọ́n wá tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, àwọn ọlọ́run àwọn èèyàn tó yí wọn ká,+ wọ́n forí balẹ̀ fún wọn, wọ́n sì múnú bí Jèhófà.+
21 Ẹ ò lè máa mu nínú ife Jèhófà* àti ife àwọn ẹ̀mí èṣù; ẹ ò lè máa jẹun lórí “tábìlì Jèhófà”*+ àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù. 22 Àbí ‘ṣé a fẹ́ máa mú Jèhófà* jowú ni’?+ A ò lágbára jù ú lọ, àbí a ní?