5 Áńgẹ́lì tí mo rí tó dúró sórí òkun àti ilẹ̀ na ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún sókè ọ̀run, 6 ó sì fi Ẹni tó wà láàyè títí láé àti láéláé+ búra, ẹni tó dá ọ̀run àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀, ayé àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú òkun àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀,+ ó sọ pé: “A ò ní fi falẹ̀ mọ́.