3 Jèhófà Ọlọ́run rẹ ló máa sọdá ṣáájú rẹ, òun fúnra rẹ̀ máa pa àwọn orílẹ̀-èdè yìí run kúrò níwájú rẹ, wàá sì lé wọn kúrò.+ Jóṣúà ló máa kó yín sọdá,+ bí Jèhófà ṣe sọ gẹ́lẹ́. 4 Ohun tí Jèhófà ṣe sí Síhónì+ àti Ógù,+ àwọn ọba Ámórì àti sí ilẹ̀ wọn, nígbà tó pa wọ́n run ló máa ṣe sí wọn gẹ́lẹ́.+