13 Ó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sì mú kí àánú ṣe Ọlọ́run, ó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ojú rere, ó sì mú un pa dà sí Jerúsálẹ́mù sí ipò ọba rẹ̀.+ Mánásè sì wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.+
9 Àmọ́ tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ mi, tí ẹ pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tí ẹ sì tẹ̀ lé wọn, kódà tí àwọn èèyàn yín tí a fọ́n ká bá wà ní ìpẹ̀kun ọ̀run, màá kó wọn jọ+ láti ibẹ̀, màá sì mú wọn wá sí ibi tí mo ti yàn pé kí orúkọ mi máa wà.’+