16 Èyí jẹ́ ìdáhùn sí ohun tí ẹ béèrè lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run yín ní Hórébù, lọ́jọ́ tí ẹ pé jọ,+ tí ẹ sọ pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí n gbọ́ ohùn Jèhófà Ọlọ́run mi mọ́, má sì jẹ́ kí n rí iná ńlá yìí mọ́, kí n má bàa kú.’+ 17 Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Ohun tí wọ́n sọ dáa.