12 “Ní báyìí, ìwọ Ísírẹ́lì, kí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ kí o ṣe?+ Kò ju pé: kí o máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ kí o máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí o máa fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+
4 Jèhófà Ọlọ́run yín ni kí ẹ máa tọ̀ lẹ́yìn, òun ni kí ẹ máa bẹ̀rù, àwọn àṣẹ rẹ̀ ni kí ẹ máa pa mọ́, ohùn rẹ̀ sì ni kí ẹ máa fetí sí; òun ni kí ẹ máa sìn, òun sì ni kí ẹ rọ̀ mọ́.+