16 Ó sì dájú pé ẹ máa mú lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín,+ àwọn ọmọbìnrin wọn máa bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe, wọ́n á sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe.+
4 Nígbà tí Sólómọ́nì darúgbó,+ àwọn ìyàwó rẹ̀ mú kí ọkàn rẹ̀ fà sí títẹ̀lé àwọn ọlọ́run míì,+ kò sì fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bíi Dáfídì bàbá rẹ̀.