3 Kí ló dé tí Jèhófà fẹ́ mú wa wá sí ilẹ̀ yìí kí wọ́n lè fi idà+ pa wá? Wọ́n á kó+ àwọn ìyàwó wa àti àwọn ọmọ wa lẹ́rú. Ǹjẹ́ kò ní dáa ká pa dà sí Íjíbítì?”+ 4 Wọ́n tiẹ̀ ń sọ fún ara wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká yan ẹnì kan ṣe olórí wa, ká sì pa dà sí Íjíbítì!”+