17 Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn nǹkan yìí nínú àwọn ìlú* yín: ìdá mẹ́wàá ọkà yín, wáìnì tuntun yín, òróró yín, àwọn àkọ́bí lára ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran yín,+ èyíkéyìí lára àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́, àwọn ọrẹ àtinúwá yín àti ọrẹ látọwọ́ yín.
19 “Gbogbo àkọ́bí tó jẹ́ akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti nínú agbo ẹran rẹ ni kí o yà sọ́tọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ O ò gbọ́dọ̀ fi àkọ́bí nínú ọ̀wọ́ ẹran* rẹ ṣe iṣẹ́ kankan, o ò sì gbọ́dọ̀ rẹ́ irun àkọ́bí nínú agbo ẹran rẹ.