ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 14:39-45
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 39 Nígbà tí Mósè sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀fọ̀ gidigidi. 40 Síbẹ̀, wọ́n dìde ní àárọ̀ kùtù, wọ́n sì gbìyànjú láti lọ sórí òkè náà, wọ́n sọ pé: “A ti ṣe tán láti lọ síbi tí Jèhófà sọ, torí a ti ṣẹ̀.”+ 41 Àmọ́ Mósè sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe kọjá ohun tí Jèhófà pa láṣẹ? Ohun tí ẹ fẹ́ ṣe yìí kò ní yọrí sí rere. 42 Ẹ má gòkè lọ, torí Jèhófà ò sí pẹ̀lú yín; ṣe ni àwọn ọ̀tá+ yín máa ṣẹ́gun yín. 43 Àwọn ọmọ Ámálékì àti àwọn ọmọ Kénáánì máa bá yín jà,+ wọ́n á sì fi idà ṣẹ́gun yín. Torí pé ẹ ti fi Jèhófà sílẹ̀, Jèhófà ò ní tì yín lẹ́yìn.”+

      44 Síbẹ̀, wọ́n ṣorí kunkun,* wọ́n sì lọ sí orí òkè+ náà, àmọ́ àpótí májẹ̀mú Jèhófà àti Mósè kò kúrò ní àárín ibùdó.+ 45 Àwọn ọmọ Ámálékì àti àwọn ọmọ Kénáánì tí wọ́n ń gbé ní òkè yẹn wá sọ̀ kalẹ̀, wọ́n bá wọn jà, wọ́n sì ń tú wọn ká títí lọ dé Hóómà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́