18 Àmọ́ Édómù sọ fún un pé: “Má gba ilẹ̀ wa kọjá. Tí o bá gbabẹ̀, idà ni màá wá fi pàdé rẹ.” 19 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fèsì pé: “Ojú pópó la máa gbà kọjá, tí àwa àtàwọn ẹran ọ̀sìn wa bá tiẹ̀ mu omi rẹ, a máa san owó rẹ̀.+ Kò sí nǹkan míì tá a fẹ́ ju pé ká fi ẹsẹ̀ wa rìn kọjá.”+