17 Wọ́n tún ń sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná,+ wọ́n ń woṣẹ́,+ wọ́n ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀, wọ́n pinnu* láti máa ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un bínú.
16 Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí à ń lọ síbi àdúrà, ìránṣẹ́bìnrin kan tó ní ẹ̀mí kan, ẹ̀mí èṣù ìwoṣẹ́,+ pàdé wa. Ó máa ń fi iṣẹ́ wíwò* mú èrè púpọ̀ wá fún àwọn ọ̀gá rẹ̀.