22 “Tí ẹ bá pa àṣẹ yìí tí mò ń pa fún yín mọ́ délẹ̀délẹ̀, tí ẹ sì ń tẹ̀ lé e, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, kí ẹ sì rọ̀ mọ́ ọn,+ 23 Jèhófà máa lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí kúrò níwájú yín,+ ẹ sì máa lé àwọn orílẹ̀-èdè tó tóbi, tí wọ́n sì pọ̀ jù yín lọ kúrò.+