-
Diutarónómì 21:6-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Kí gbogbo àgbààgbà ìlú tó sún mọ́ òkú náà jù wá fọ ọwọ́ wọn+ sórí ọmọ màlúù náà, èyí tí wọ́n ṣẹ́ ọrùn rẹ̀ ní àfonífojì, 7 kí wọ́n sì kéde pé, ‘Ọwọ́ wa kọ́ ló ta ẹ̀jẹ̀ yìí sílẹ̀, ojú wa ò sì rí i nígbà tí wọ́n ta á sílẹ̀. 8 Jèhófà, má ṣe kà á sí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì lọ́rùn, àwọn tí o rà pa dà,+ má sì jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀.’+ A ò sì ní ka ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ náà sí wọn lọ́rùn. 9 Èyí lo fi máa mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ kúrò ní àárín rẹ, torí pé o ṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà.
-